Isaiah 11:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òun yóò gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Israẹli jọ, yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí a ti fọ́n káàkiri jọ, láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.
Isaiah 11:12 in English
Isaiah 11:12 · Berean Standard Bible
He will raise a banner for the nations and gather the exiles of Israel; He will collect the scattered of Judah from the four corners of the earth.
Context
10Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo. 11Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Asiria wá, láti ìsàlẹ̀ Ejibiti àti òkè Ejibiti, láti Kuṣi, láti Elamu láti Babiloni, láti Hamati àti láti àwọn erékùṣù inú Òkun. 12Òun yóò gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè,
yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Israẹli jọ,
yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí a ti fọ́n káàkiri jọ,
láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé. 13Owú jíjẹ Efraimu yóò pòórá,
àwọn ọ̀tá Juda ni a ó ké kúrò,
Efraimu kò ní jowú Juda,
tàbí Juda kó dojúkọ Efraimu. 14Wọn yóò fò mọ́ èjìká Filistini
sí apá ìwọ̀-oòrùn,
wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọn
ènìyàn apá ìlà-oòrùn.
Wọn yóò gbé ọwọ́ wọn lé Edomu àti Moabu,
àwọn ará Ammoni yóò sì di ìwẹ̀fà wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.