Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Owú jíjẹ Efraimu yóò pòórá, àwọn ọ̀tá Juda ni a ó ké kúrò, Efraimu kò ní jowú Juda, tàbí Juda kó dojúkọ Efraimu.

Isaiah 11:13 in English

Isaiah 11:13 · Berean Standard Bible

Then the jealousy of Ephraim * will depart, and the adversaries * of Judah will be cut off. Ephraim will no longer envy Judah, nor will Judah harass Ephraim.

Context

11Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Asiria wá, láti ìsàlẹ̀ Ejibiti àti òkè Ejibiti, láti Kuṣi, láti Elamu láti Babiloni, láti Hamati àti láti àwọn erékùṣù inú Òkun. 12Òun yóò gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Israẹli jọ, yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí a ti fọ́n káàkiri jọ, láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé. 13Owú jíjẹ Efraimu yóò pòórá, àwọn ọ̀tá Juda ni a ó ké kúrò, Efraimu kò ní jowú Juda, tàbí Juda kó dojúkọ Efraimu. 14Wọn yóò fò mọ́ èjìká Filistini sí apá ìwọ̀-oòrùn, wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọn ènìyàn apá ìlà-oòrùn. Wọn yóò gbé ọwọ́ wọn lé Edomu àti Moabu, àwọn ará Ammoni yóò sì di ìwẹ̀fà wọn. 15Olúwa yóò sọ di gbígbé àyasí Òkun Ejibiti, pẹ̀lú atẹ́gùn gbígbóná ni yóò na ọwọ́ rẹ̀, kọjá lórí odò Eufurate. Òun yóò sì sọ ọ́ di ọmọdò méje tó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn yóò máa là á kọjá pẹ̀lú bàtà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.