Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run ní gbogbo òkè mímọ́ mi, nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun.

Isaiah 11:9 in English

Isaiah 11:9 · Berean Standard Bible

They will neither harm nor destroy on all My holy mountain, for the earth will be full of the knowledge of the LORD as the sea is full of water.

Context

7Màlúù àti beari yóò máa jẹun pọ̀, àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀, kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù. 8Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká, ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀. 9Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run ní gbogbo òkè mímọ́ mi, nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun. 10Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo. 11Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Asiria wá, láti ìsàlẹ̀ Ejibiti àti òkè Ejibiti, láti Kuṣi, láti Elamu láti Babiloni, láti Hamati àti láti àwọn erékùṣù inú Òkun.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.