Isaiah 11:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká, ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀.
Isaiah 11:8 in English
Isaiah 11:8 · Berean Standard Bible
The infant will play by the cobra’s den, and the toddler will reach into the viper’s nest.
Context
6Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé,
ẹkùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́
ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún
àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀
ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n. 7Màlúù àti beari yóò máa jẹun pọ̀,
àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀,
kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko
gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù. 8Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká,
ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀. 9Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run
ní gbogbo òkè mímọ́ mi,
nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa
gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun. 10Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.