Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé, ẹkùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́ ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀ ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n.

Isaiah 11:6 in English

Isaiah 11:6 · Berean Standard Bible

The wolf will live with the lamb, and the leopard will lie down with the goat; the calf and young lion and fatling will be together,* and a little child will lead them.

Context

4ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní, pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu fún àwọn aláìní ayé. Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀, pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà. 5Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀ àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká. 6Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé, ẹkùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́ ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀ ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n. 7Màlúù àti beari yóò máa jẹun pọ̀, àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀, kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù. 8Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká, ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.