Hosea 7:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ègbé ní fún wọn, nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìparun wà lórí wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi! Èmi fẹ́ láti rà wọ́n padà. Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi.
Hosea 7:13 in English
Hosea 7:13 · Berean Standard Bible
Woe to them, for they have strayed from Me! Destruction to them, for they have rebelled against Me! Though I would redeem them, they speak lies against Me.
Context
11“Efraimu dàbí àdàbà
tó rọrùn láti tànjẹ àti aláìgbọ́n
tó wá ń pé Ejibiti nísinsin yìí
tó sì tún ń padà lọ si Asiria. 12Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọn,
Èmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀run.
Nígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀,
Èmi ó nà wọ́n fún iṣẹ́ búburú ọwọ́ wọn. 13Ègbé ní fún wọn,
nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi!
Ìparun wà lórí wọn,
nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi!
Èmi fẹ́ láti rà wọ́n padà.
Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi. 14Wọn kò kégbe pè mí láti ọkàn wọn,
ṣùgbọ́n wọ́n ń pohùnréré ẹkún lórí ibùsùn wọn.
Wọ́n kó ara wọn jọ, nítorí ọkà àti wáìnì
ṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ mi. 15Mo kọ́ wọn, mo sì fún wọn ní agbára,
síbẹ̀ wọ́n tún ń dìtẹ̀ mọ́ mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.