Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọn, Èmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀run. Nígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀, Èmi ó nà wọ́n fún iṣẹ́ búburú ọwọ́ wọn.

Hosea 7:12 in English

Hosea 7:12 · Berean Standard Bible

As they go, I will spread My net over them; I will bring them down like birds of the air. I will chastise them when I hear them flocking together.*

Context

10Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí sí i ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí kò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run, tàbí kí ó wá a. 11“Efraimu dàbí àdàbà tó rọrùn láti tànjẹ àti aláìgbọ́n tó wá ń pé Ejibiti nísinsin yìí tó sì tún ń padà lọ si Asiria. 12Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọn, Èmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀run. Nígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀, Èmi ó nà wọ́n fún iṣẹ́ búburú ọwọ́ wọn. 13Ègbé ní fún wọn, nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìparun wà lórí wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi! Èmi fẹ́ láti rà wọ́n padà. Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi. 14Wọn kò kégbe pè mí láti ọkàn wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ń pohùnréré ẹkún lórí ibùsùn wọn. Wọ́n kó ara wọn jọ, nítorí ọkà àti wáìnì ṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.