Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Efraimu dàbí àdàbà tó rọrùn láti tànjẹ àti aláìgbọ́n tó wá ń pé Ejibiti nísinsin yìí tó sì tún ń padà lọ si Asiria.

Hosea 7:11 in English

Hosea 7:11 · Berean Standard Bible

So Ephraim has become like a silly, senseless dove— calling out to Egypt, then turning to Assyria.

Context

9Àwọn àlejò ti jẹ agbára rẹ̀ run ṣùgbọ́n kò sì mọ̀. Ewú ti wà ní orí rẹ̀ káàkiri bẹ́ẹ̀ ni kò kíyèsi i. 10Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí sí i ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí kò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run, tàbí kí ó wá a. 11“Efraimu dàbí àdàbà tó rọrùn láti tànjẹ àti aláìgbọ́n tó wá ń pé Ejibiti nísinsin yìí tó sì tún ń padà lọ si Asiria. 12Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọn, Èmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀run. Nígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀, Èmi ó nà wọ́n fún iṣẹ́ búburú ọwọ́ wọn. 13Ègbé ní fún wọn, nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìparun wà lórí wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi! Èmi fẹ́ láti rà wọ́n padà. Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.