Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí sí i ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí kò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run, tàbí kí ó wá a.

Hosea 7:10 in English

Hosea 7:10 · Berean Standard Bible

Israel’s arrogance testifies against them, yet they do not return to the LORD their God; despite all this, they do not seek Him.

Context

8“Efraimu ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà; Efraimu jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà. 9Àwọn àlejò ti jẹ agbára rẹ̀ run ṣùgbọ́n kò sì mọ̀. Ewú ti wà ní orí rẹ̀ káàkiri bẹ́ẹ̀ ni kò kíyèsi i. 10Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí sí i ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí kò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run, tàbí kí ó wá a. 11“Efraimu dàbí àdàbà tó rọrùn láti tànjẹ àti aláìgbọ́n tó wá ń pé Ejibiti nísinsin yìí tó sì tún ń padà lọ si Asiria. 12Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọn, Èmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀run. Nígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀, Èmi ó nà wọ́n fún iṣẹ́ búburú ọwọ́ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.