Hosea 7:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Efraimu ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà; Efraimu jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà.
Hosea 7:8 in English
Hosea 7:8 · Berean Standard Bible
Ephraim mixes with the nations; Ephraim is an unturned cake.
Context
6Ọkàn wọn ń gbóná bí i ààrò
wọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú rìkíṣí,
ìbínú wọn pa lọ́lọ́ ní gbogbo òru
ó sì bú jáde bí ọ̀wọ́-iná ní òwúrọ̀. 7Gbogbo wọn gbóná bí ààrò
wọ́n pa gbogbo olórí wọn run,
gbogbo ọba wọn si ṣubú
kò sì ṣí ẹnìkan nínú wọn tí ó ké pè mí. 8“Efraimu ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà;
Efraimu jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà. 9Àwọn àlejò ti jẹ agbára rẹ̀ run
ṣùgbọ́n kò sì mọ̀.
Ewú ti wà ní orí rẹ̀ káàkiri
bẹ́ẹ̀ ni kò kíyèsi i. 10Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí sí i
ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí
kò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa
Ọlọ́run, tàbí kí ó wá a.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.