Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo kọ́ wọn, mo sì fún wọn ní agbára, síbẹ̀ wọ́n tún ń dìtẹ̀ mọ́ mi.

Hosea 7:15 in English

Hosea 7:15 · Berean Standard Bible

Although I trained and strengthened their arms, they plot evil against Me.

Context

13Ègbé ní fún wọn, nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìparun wà lórí wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi! Èmi fẹ́ láti rà wọ́n padà. Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi. 14Wọn kò kégbe pè mí láti ọkàn wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ń pohùnréré ẹkún lórí ibùsùn wọn. Wọ́n kó ara wọn jọ, nítorí ọkà àti wáìnì ṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ mi. 15Mo kọ́ wọn, mo sì fún wọn ní agbára, síbẹ̀ wọ́n tún ń dìtẹ̀ mọ́ mi. 16Wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ Ọ̀gá-ògo; wọ́n dàbí ọfà tí ó ti bàjẹ́. Àwọn aṣíwájú wọn yóò ti ipa idà ṣubú nítorí ìrunú ahọ́n wọn. Torí èyí, wọn ó fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà ní ilẹ̀ Ejibiti.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.