Hosea 4:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ ń ṣubú lọ́sàn án àti lóru àwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lú yín. Èmi ó pa ìyá rẹ run,
Hosea 4:5 in English
Hosea 4:5 · Berean Standard Bible
You will stumble by day, and the prophet will stumble with you by night; so I will destroy your mother—
Context
3Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀,
gbogbo olùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù.
Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run
àti ẹja inú omi ló ń kú. 4“Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá,
kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹnìkejì
nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbí
àwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà. 5Ẹ ń ṣubú lọ́sàn án àti lóru
àwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lú yín.
Èmi ó pa ìyá rẹ run, 6àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀.
“Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀.
Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi;
nítorí pé ẹ ti kọ òfin Ọlọ́run yín sílẹ̀,
Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín. 7Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí i
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi.
Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.