Hosea 4:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo olùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù. Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹja inú omi ló ń kú.
Hosea 4:3 in English
Hosea 4:3 · Berean Standard Bible
Therefore the land mourns, and all who dwell in it will waste away with the beasts of the field and the birds of the air; even the fish of the sea disappear.
Context
1Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọmọ Israẹli,
nítorí pé Olúwa fi ẹ̀sùn
kan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà.
“Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́,
Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà, 2àfi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyàn
olè jíjà àti panṣágà.
Wọ́n rú gbogbo òfin,
ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀. 3Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀,
gbogbo olùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù.
Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run
àti ẹja inú omi ló ń kú. 4“Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá,
kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹnìkejì
nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbí
àwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà. 5Ẹ ń ṣubú lọ́sàn án àti lóru
àwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lú yín.
Èmi ó pa ìyá rẹ run,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.