Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀. “Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀. Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi; nítorí pé ẹ ti kọ òfin Ọlọ́run yín sílẹ̀, Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín.

Hosea 4:6 in English

Hosea 4:6 · Berean Standard Bible

My people are destroyed for lack of knowledge. Because you have rejected knowledge, I will also reject you as My priests. Since you have forgotten the law of your God, I will also forget your children.

Context

4“Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá, kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹnìkejì nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbí àwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà. 5Ẹ ń ṣubú lọ́sàn án àti lóru àwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lú yín. Èmi ó pa ìyá rẹ run, 6àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀. “Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀. Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi; nítorí pé ẹ ti kọ òfin Ọlọ́run yín sílẹ̀, Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín. 7Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí i bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi. Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú 8wọ́n ń jẹun nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi, wọ́n sì ń gbádùn nínú ìwà búburú wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.