Hosea 2:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni àti ẹni tó fún un ní ọkà, ọtí wáìnì tuntun àti òróró ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọ́pọ̀, èyí tí wọ́n lò fún Baali.
Hosea 2:8 in English
Hosea 2:8 · Berean Standard Bible
For she does not acknowledge that it was I who gave her grain, new wine, and oil, who lavished on her silver and gold— which they crafted for Baal.
Context
6Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà,
Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ. 7Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn;
yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn.
Nígbà náà ni yóò sọ pé,
‘Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́
nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsin yìí lọ.’ 8Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni
àti ẹni tó fún un ní ọkà,
ọtí wáìnì tuntun àti òróró
ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọ́pọ̀, èyí tí wọ́n lò fún Baali. 9“Nítorí náà, èmi yóò mú ọkà mi kúrò nígbà tó bá pọ́n,
èmi yóò sì mú wáìnì mi kúrò ní àsìkò rẹ̀.
Èmi yóò sì gba irun àgùntàn àti ọ̀gbọ̀ mi padà
ti mo ti fi fún un láti bo ìhòhò rẹ̀. 10Èmi yóò sì fi ìwà ìtìjú rẹ̀ hàn
lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀
kò sí ẹni tí yóò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.