Hosea 2:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà, Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ.
Hosea 2:6 in English
Hosea 2:6 · Berean Standard Bible
Therefore, behold, I will hedge up her path * with thorns; I will enclose her with a wall, so she cannot find her way.
Context
4Èmi kò ní fi àánú mi hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀
nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n jẹ́. 5Nítorí ìyá wọn ti hùwà àgbèrè,
ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú.
Ó wí pé, ‘Èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi lẹ́yìn,
tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi,
ní irun àgùntàn mi àti ọ̀gbọ̀ mi,
òróró mi àti ohun mímu mi.’ 6Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà,
Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ. 7Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn;
yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn.
Nígbà náà ni yóò sọ pé,
‘Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́
nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsin yìí lọ.’ 8Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni
àti ẹni tó fún un ní ọkà,
ọtí wáìnì tuntun àti òróró
ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọ́pọ̀, èyí tí wọ́n lò fún Baali.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.