Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn; yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn. Nígbà náà ni yóò sọ pé, ‘Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́ nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsin yìí lọ.’

Hosea 2:7 in English

Hosea 2:7 · Berean Standard Bible

She will pursue her lovers but not catch them; she will seek them but not find them. Then she will say, ‘I will return to my first husband, for then I was better off than now.’

Context

5Nítorí ìyá wọn ti hùwà àgbèrè, ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú. Ó wí pé, ‘Èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi lẹ́yìn, tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi, ní irun àgùntàn mi àti ọ̀gbọ̀ mi, òróró mi àti ohun mímu mi.’ 6Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà, Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ. 7Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn; yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn. Nígbà náà ni yóò sọ pé, ‘Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́ nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsin yìí lọ.’ 8Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni àti ẹni tó fún un ní ọkà, ọtí wáìnì tuntun àti òróró ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọ́pọ̀, èyí tí wọ́n lò fún Baali. 9“Nítorí náà, èmi yóò mú ọkà mi kúrò nígbà tó bá pọ́n, èmi yóò sì mú wáìnì mi kúrò ní àsìkò rẹ̀. Èmi yóò sì gba irun àgùntàn àti ọ̀gbọ̀ mi padà ti mo ti fi fún un láti bo ìhòhò rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.