Hosea 2:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi kò ní fi àánú mi hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀ nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n jẹ́.
Hosea 2:4 in English
Hosea 2:4 · Berean Standard Bible
I will have no compassion on her children, because they are the children of adultery.
Context
2“Ẹ bá ìyá yín wí, ẹ bá a wí,
nítorí pé kì í ṣe ìyàwó mi,
Èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀.
Jẹ́ kí ó yọ àgbèrè rẹ̀ kúrò lójú rẹ̀
àti àìṣòótọ́ kúrò ní àyà rẹ̀. 3Àìṣe bẹ́ẹ̀ èmi yóò tú u sí ìhòhò,
Èmi yóò sì gbé e kalẹ̀ bí ọjọ́ tí a bí i.
Èmi yóò ṣe ọ́ bí i aṣálẹ̀ ilẹ̀,
Èmi yóò sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀
Èmi yóò sì fi òǹgbẹ gbẹ ẹ́. 4Èmi kò ní fi àánú mi hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀
nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n jẹ́. 5Nítorí ìyá wọn ti hùwà àgbèrè,
ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú.
Ó wí pé, ‘Èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi lẹ́yìn,
tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi,
ní irun àgùntàn mi àti ọ̀gbọ̀ mi,
òróró mi àti ohun mímu mi.’ 6Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà,
Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.