Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò sì fi ìwà ìtìjú rẹ̀ hàn lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kò sí ẹni tí yóò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi,

Hosea 2:10 in English

Hosea 2:10 · Berean Standard Bible

And then I will expose her lewdness in the sight of her lovers, and no one will deliver her out of My hands.

Context

8Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni àti ẹni tó fún un ní ọkà, ọtí wáìnì tuntun àti òróró ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọ́pọ̀, èyí tí wọ́n lò fún Baali. 9“Nítorí náà, èmi yóò mú ọkà mi kúrò nígbà tó bá pọ́n, èmi yóò sì mú wáìnì mi kúrò ní àsìkò rẹ̀. Èmi yóò sì gba irun àgùntàn àti ọ̀gbọ̀ mi padà ti mo ti fi fún un láti bo ìhòhò rẹ̀. 10Èmi yóò sì fi ìwà ìtìjú rẹ̀ hàn lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kò sí ẹni tí yóò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi, 11Èmi yóò mú gbogbo ayọ̀ rẹ̀ wá sí òpin: àjọ̀dún ọdọọdún rẹ̀, oṣù tuntun rẹ̀, ọjọ́ ìsinmi, àti gbogbo àwọn àjọ̀dún tí a yàn. 12Èmi yóò pa àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ run, èyí tí ó pè ní èrè rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, Èmi yóò sọ wọ́n di igbó, àwọn ẹranko búburú yóò sì jẹ́ wọn run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.