Hosea 13:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo ṣe ìtọ́jú rẹ ní aginjù, ní ilẹ̀ tí ó gbẹ tí kò ní omi.
Hosea 13:5 in English
Hosea 13:5 · Berean Standard Bible
I knew you in the wilderness, in the land of drought.
Context
3Nítorí náà wọn yóò dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀,
bí ìrì òwúrọ̀ kùtùkùtù tó máa ń parẹ́,
bí i èèpo ìyẹ̀fun tí afẹ́fẹ́ gbé láti ibi ìpakà
bí èéfín tó rú jáde gba ojú fèrèsé. 4“Ṣùgbọ́n Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ̀,
ẹni tó mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá.
Ìwọ̀ kì yóò sì mọ ọlọ́run mìíràn àfi èmi
kò sí olùgbàlà mìíràn lẹ́yìn mi. 5Mo ṣe ìtọ́jú rẹ ní aginjù,
ní ilẹ̀ tí ó gbẹ tí kò ní omi. 6Wọn ni ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí mo fún wọn ní oúnjẹ,
Nígbà tí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn tan wọ́n di agbéraga.
Nígbà náà ni wọ́n sì gbàgbé mi. 7Nítorí náà, Èmi yóò dìde sí wọn bí i kìnnìún,
Èmi yóò fi ara pamọ́ dè wọ́n lọ́nà bí i ẹkùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.