Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà wọn yóò dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀, bí ìrì òwúrọ̀ kùtùkùtù tó máa ń parẹ́, bí i èèpo ìyẹ̀fun tí afẹ́fẹ́ gbé láti ibi ìpakà bí èéfín tó rú jáde gba ojú fèrèsé.

Hosea 13:3 in English

Hosea 13:3 · Berean Standard Bible

Therefore they will be like the morning mist, like the early dew that vanishes, like chaff blown from a threshing floor, like smoke through an open window.

Context

1Nígbà ti Efraimu bá ń sọ̀rọ̀, àwọn ènìyàn máa ń wárìrì, a gbé e ga ní Israẹli ṣùgbọ́n ó jẹ̀bi ẹ̀sùn pé ó ń sin òrìṣà Baali, ó sì kú. 2Báyìí, wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀; wọn fi fàdákà ṣe ère òrìṣà fúnra wọn; ère tí a fi ọgbọ́n dá àrà sí, gbogbo wọn jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà. Wọn ń sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Pé, “Jẹ́ kí àwọn ènìyàn tí ń rú ẹbọ fi ẹnu, ko àwọn ẹgbọrọ màlúù ni ẹnu.” 3Nítorí náà wọn yóò dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀, bí ìrì òwúrọ̀ kùtùkùtù tó máa ń parẹ́, bí i èèpo ìyẹ̀fun tí afẹ́fẹ́ gbé láti ibi ìpakà bí èéfín tó rú jáde gba ojú fèrèsé. 4“Ṣùgbọ́n Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ẹni tó mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá. Ìwọ̀ kì yóò sì mọ ọlọ́run mìíràn àfi èmi kò sí olùgbàlà mìíràn lẹ́yìn mi. 5Mo ṣe ìtọ́jú rẹ ní aginjù, ní ilẹ̀ tí ó gbẹ tí kò ní omi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.