Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọn ni ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí mo fún wọn ní oúnjẹ, Nígbà tí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn tan wọ́n di agbéraga. Nígbà náà ni wọ́n sì gbàgbé mi.

Hosea 13:6 in English

Hosea 13:6 · Berean Standard Bible

When they had pasture, they became satisfied; when they were satisfied, their hearts became proud, and as a result they forgot Me.

Context

4“Ṣùgbọ́n Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ẹni tó mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá. Ìwọ̀ kì yóò sì mọ ọlọ́run mìíràn àfi èmi kò sí olùgbàlà mìíràn lẹ́yìn mi. 5Mo ṣe ìtọ́jú rẹ ní aginjù, ní ilẹ̀ tí ó gbẹ tí kò ní omi. 6Wọn ni ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí mo fún wọn ní oúnjẹ, Nígbà tí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn tan wọ́n di agbéraga. Nígbà náà ni wọ́n sì gbàgbé mi. 7Nítorí náà, Èmi yóò dìde sí wọn bí i kìnnìún, Èmi yóò fi ara pamọ́ dè wọ́n lọ́nà bí i ẹkùn. 8Beari igbó tí a já ọmọ rẹ̀ gbà, Èmi yóò bá wọn jà bí? Èmi yóò sì fà wọ́n ya bí ìgbà tí ẹkùn bá fa ara wọn ya bi ẹranko búburú ni èmi yóò fa wọn ya.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.