Hosea 10:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí igi tó léfòó lórí omi ni Samaria àti àwọn ọba rẹ yóò sàn lọ.
Hosea 10:7 in English
Hosea 10:7 · Berean Standard Bible
Samaria will be carried off with her king like a twig on the surface of the water.
Context
5Àwọn ènìyàn tí ń gbé Samaria bẹ̀rù
nítorí ère abo màlúù tó wà ní Beti-Afeni.
Àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ le e lórí
bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rẹ̀.
Gbogbo àwọn tó láyọ̀ sì dídán rẹ̀,
nítorí tí a ti mú lọ sí ìgbèkùn. 6A ó gbé lọ sí Asiria
gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọba ńlá
a ó dójútì Efraimu;
ojú yóò ti Israẹli nítorí ìgbìmọ̀ rẹ̀. 7Bí igi tó léfòó lórí omi ni
Samaria àti àwọn ọba rẹ yóò sàn lọ. 8Àwọn ibi gíga tí ẹ tí ń hùwà búburú ni a o parun,
èyí ni ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli.
Ẹ̀gún ọ̀gàn àti ẹ̀gún òṣùṣú yóò hù jáde,
yóò sì bo àwọn pẹpẹ wọn.
Wọn yóò sọ fún àwọn òkè gíga pé, “Bò wá mọ́lẹ̀!”
àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, “Ṣubú lù wá!” 9“Láti ìgbà Gibeah, ni ó ti ṣẹ̀, ìwọ Israẹli,
ìwọ sì tún wà níbẹ̀.
Ǹjẹ́ ogun kò lé ẹ̀yin aṣebi
ni Gibeah bá bí?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.