Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ibi gíga tí ẹ tí ń hùwà búburú ni a o parun, èyí ni ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli. Ẹ̀gún ọ̀gàn àti ẹ̀gún òṣùṣú yóò hù jáde, yóò sì bo àwọn pẹpẹ wọn. Wọn yóò sọ fún àwọn òkè gíga pé, “Bò wá mọ́lẹ̀!” àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, “Ṣubú lù wá!”

Hosea 10:8 in English

Hosea 10:8 · Berean Standard Bible

The high places of Aven * will be destroyed— it is the sin of Israel; thorns and thistles will overgrow their altars. Then they will say to the mountains, “Cover us!” and to the hills, “Fall on us!”*

Context

6A ó gbé lọ sí Asiria gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọba ńlá a ó dójútì Efraimu; ojú yóò ti Israẹli nítorí ìgbìmọ̀ rẹ̀. 7Bí igi tó léfòó lórí omi ni Samaria àti àwọn ọba rẹ yóò sàn lọ. 8Àwọn ibi gíga tí ẹ tí ń hùwà búburú ni a o parun, èyí ni ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli. Ẹ̀gún ọ̀gàn àti ẹ̀gún òṣùṣú yóò hù jáde, yóò sì bo àwọn pẹpẹ wọn. Wọn yóò sọ fún àwọn òkè gíga pé, “Bò wá mọ́lẹ̀!” àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, “Ṣubú lù wá!” 9“Láti ìgbà Gibeah, ni ó ti ṣẹ̀, ìwọ Israẹli, ìwọ sì tún wà níbẹ̀. Ǹjẹ́ ogun kò lé ẹ̀yin aṣebi ni Gibeah bá bí? 10Nígbà tó bá tẹ́ mi lọ́rùn, èmi yóò fi ìyà jẹ wọ́n; Orílẹ̀-èdè yóò kó ra wọn jọ, wọ́n ó sì dojúkọ wọn, láti fi wọn sínú ìdè nítorí ìlọ́po ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.