Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ènìyàn tí ń gbé Samaria bẹ̀rù nítorí ère abo màlúù tó wà ní Beti-Afeni. Àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ le e lórí bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rẹ̀. Gbogbo àwọn tó láyọ̀ sì dídán rẹ̀, nítorí tí a ti mú lọ sí ìgbèkùn.

Hosea 10:5 in English

Hosea 10:5 · Berean Standard Bible

The people of Samaria will fear for the calf of Beth-aven.* Indeed, its people will mourn with its idolatrous priests— those who rejoiced in its glory— for it has been taken from them into exile.

Context

3Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, “A kò ní ọba nítorí tí a kò bọ̀wọ̀ fún Olúwa ṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ní ọba, kí ni yóò ṣe fún wa?” 4Wọ́n ṣe ìlérí púpọ̀, wọ́n ṣe ìbúra èké, wọ́n da májẹ̀mú; báyìí ni ìdájọ́ hù sókè bí igi ìwọ̀ ni aporo oko, bi i koríko májèlé láàrín oko tí a ro. 5Àwọn ènìyàn tí ń gbé Samaria bẹ̀rù nítorí ère abo màlúù tó wà ní Beti-Afeni. Àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ le e lórí bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rẹ̀. Gbogbo àwọn tó láyọ̀ sì dídán rẹ̀, nítorí tí a ti mú lọ sí ìgbèkùn. 6A ó gbé lọ sí Asiria gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọba ńlá a ó dójútì Efraimu; ojú yóò ti Israẹli nítorí ìgbìmọ̀ rẹ̀. 7Bí igi tó léfòó lórí omi ni Samaria àti àwọn ọba rẹ yóò sàn lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.