Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, “A kò ní ọba nítorí tí a kò bọ̀wọ̀ fún Olúwa ṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ní ọba, kí ni yóò ṣe fún wa?”

Hosea 10:3 in English

Hosea 10:3 · Berean Standard Bible

Surely now they will say, “We have no king, for we do not revere the LORD. What can a king do for us?”

Context

1Israẹli jẹ́ igi àjàrà tó gbilẹ̀ ó ń so èso fún ara rẹ̀. Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí i bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rere o bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀. 2Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹ báyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn. Olúwa yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀ yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run. 3Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, “A kò ní ọba nítorí tí a kò bọ̀wọ̀ fún Olúwa ṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ní ọba, kí ni yóò ṣe fún wa?” 4Wọ́n ṣe ìlérí púpọ̀, wọ́n ṣe ìbúra èké, wọ́n da májẹ̀mú; báyìí ni ìdájọ́ hù sókè bí igi ìwọ̀ ni aporo oko, bi i koríko májèlé láàrín oko tí a ro. 5Àwọn ènìyàn tí ń gbé Samaria bẹ̀rù nítorí ère abo màlúù tó wà ní Beti-Afeni. Àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ le e lórí bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rẹ̀. Gbogbo àwọn tó láyọ̀ sì dídán rẹ̀, nítorí tí a ti mú lọ sí ìgbèkùn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.