Hosea 10:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹ báyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn. Olúwa yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀ yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run.
Hosea 10:2 in English
Hosea 10:2 · Berean Standard Bible
Their hearts are devious; now they must bear their guilt. The LORD will break down their altars and demolish their sacred pillars.
Context
1Israẹli jẹ́ igi àjàrà tó gbilẹ̀
ó ń so èso fún ara rẹ̀.
Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀
bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí i
bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rere
o bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀. 2Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹ
báyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn.
Olúwa yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀
yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run. 3Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, “A kò ní ọba
nítorí tí a kò bọ̀wọ̀ fún Olúwa
ṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ní ọba,
kí ni yóò ṣe fún wa?” 4Wọ́n ṣe ìlérí púpọ̀,
wọ́n ṣe ìbúra èké,
wọ́n da májẹ̀mú;
báyìí ni ìdájọ́ hù sókè bí igi ìwọ̀ ni aporo oko,
bi i koríko májèlé láàrín oko tí a ro.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.