Native Bible

Hebrews 1:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ó sọ nípa tí Ọmọ rẹ̀ pé, “Ìtẹ́ rẹ, Ọlọ́run, láé àti láéláé ni, ọ̀pá aládé òdodo ni ọ̀pá ìjọba rẹ.

Hebrews 1:8 in English

Hebrews 1:8 · Berean Standard Bible

But about the Son He says: “Your throne, O God, endures forever and ever, and justice is the scepter of Your kingdom.

Context

6Àti pẹ̀lú, nígbà tí Ọlọ́run rán àkọ́bí rẹ̀ wá si ayé wa yìí. Ó pàṣẹ pé, “Ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn angẹli Ọlọ́run foríbalẹ̀ fún un.” 7Àti nípa ti àwọn angẹli, ó wí pé, “Ẹni tí ó dá àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀mí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.” 8Ṣùgbọ́n ó sọ nípa tí Ọmọ rẹ̀ pé, “Ìtẹ́ rẹ, Ọlọ́run, láé àti láéláé ni, ọ̀pá aládé òdodo ni ọ̀pá ìjọba rẹ. 9Ìwọ fẹ́ òdodo, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kórìíra iṣẹ́ búburú; nítorí èyí ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ ṣe fi àmì òróró ayọ̀ yàn ọ tí ó gbé ọ ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.” 10Ó tún sọ pé, “Ní àtètèkọ́ṣe, ìwọ Olúwa, ìwọ fi ìdí ayé sọlẹ̀, àwọn ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.