Heberu 1:6
Hebrews 1:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti pẹ̀lú, nígbà tí Ọlọ́run rán àkọ́bí rẹ̀ wá si ayé wa yìí. Ó pàṣẹ pé, “Ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn angẹli Ọlọ́run foríbalẹ̀ fún un.”
Hebrews 1:6 in English
Hebrews 1:6 · Berean Standard Bible
And again, when God brings His firstborn into the world, He says: “Let all God’s angels worship Him.”*
Context
4Nítorí náà, ó sì ti fi bẹ́ẹ̀ di ẹni tí ó ga ní ipò ju angẹli lọ, bí ó ti jogún orúkọ èyí tí ó tayọ̀ tiwọn. 5Nítorí kò sí ọ̀kan nínú àwọn angẹli tí Ọlọ́run fi ìgbà kan sọ fún pé:
“Ìwọ ni ọmọ mi;
lónìí ni mo bí ọ”?
Àti pẹ̀lú pé,
“Èmi yóò jẹ́ baba fún un,
Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi”? 6Àti pẹ̀lú, nígbà tí Ọlọ́run rán àkọ́bí rẹ̀ wá si ayé wa yìí. Ó pàṣẹ pé,
“Ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn angẹli Ọlọ́run foríbalẹ̀ fún un.” 7Àti nípa ti àwọn angẹli, ó wí pé,
“Ẹni tí ó dá àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀mí,
àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.” 8Ṣùgbọ́n ó sọ nípa tí Ọmọ rẹ̀ pé,
“Ìtẹ́ rẹ, Ọlọ́run, láé àti láéláé ni,
ọ̀pá aládé òdodo ni ọ̀pá ìjọba rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.