Native Bible

Hebrews 1:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ fẹ́ òdodo, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kórìíra iṣẹ́ búburú; nítorí èyí ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ ṣe fi àmì òróró ayọ̀ yàn ọ tí ó gbé ọ ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.”

Hebrews 1:9 in English

Hebrews 1:9 · Berean Standard Bible

You have loved righteousness and hated wickedness; therefore God, Your God, has anointed You above Your companions with the oil of joy.”*

Context

7Àti nípa ti àwọn angẹli, ó wí pé, “Ẹni tí ó dá àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀mí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.” 8Ṣùgbọ́n ó sọ nípa tí Ọmọ rẹ̀ pé, “Ìtẹ́ rẹ, Ọlọ́run, láé àti láéláé ni, ọ̀pá aládé òdodo ni ọ̀pá ìjọba rẹ. 9Ìwọ fẹ́ òdodo, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kórìíra iṣẹ́ búburú; nítorí èyí ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ ṣe fi àmì òróró ayọ̀ yàn ọ tí ó gbé ọ ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.” 10Ó tún sọ pé, “Ní àtètèkọ́ṣe, ìwọ Olúwa, ìwọ fi ìdí ayé sọlẹ̀, àwọn ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ. 11Wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà síbẹ̀ gbogbo wọn ni yóò di àkísà bí ẹ̀wù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.