Heberu 1:11
Hebrews 1:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà síbẹ̀ gbogbo wọn ni yóò di àkísà bí ẹ̀wù.
Hebrews 1:11 in English
Hebrews 1:11 · Berean Standard Bible
They will perish, but You remain; they will all wear out like a garment.
Context
9Ìwọ fẹ́ òdodo, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kórìíra iṣẹ́ búburú;
nítorí èyí ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ ṣe fi àmì òróró ayọ̀ yàn ọ
tí ó gbé ọ ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.” 10Ó tún sọ pé,
“Ní àtètèkọ́ṣe, ìwọ Olúwa, ìwọ fi ìdí ayé sọlẹ̀,
àwọn ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ. 11Wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà síbẹ̀
gbogbo wọn ni yóò di àkísà bí ẹ̀wù. 12Ní kíká ni ìwọ yóò ká wọn bí aṣọ,
bí ìpààrọ̀ aṣọ ni a ó sì pààrọ̀ wọn.
Ṣùgbọ́n ìwọ fúnra rẹ̀ kì yóò yípadà
àti pé ọdún rẹ kì yóò ní òpin.” 13Èwo nínú àwọn angẹli ní a gbọ́ pé Ọlọ́run fi ìgbà kan wí fún pé,
“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ”?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.