Heberu 1:13
Hebrews 1:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èwo nínú àwọn angẹli ní a gbọ́ pé Ọlọ́run fi ìgbà kan wí fún pé, “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ”?
Hebrews 1:13 in English
Hebrews 1:13 · Berean Standard Bible
Yet to which of the angels did God ever say: “Sit at My right hand until I make Your enemies a footstool for Your feet”*?
Context
11Wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà síbẹ̀
gbogbo wọn ni yóò di àkísà bí ẹ̀wù. 12Ní kíká ni ìwọ yóò ká wọn bí aṣọ,
bí ìpààrọ̀ aṣọ ni a ó sì pààrọ̀ wọn.
Ṣùgbọ́n ìwọ fúnra rẹ̀ kì yóò yípadà
àti pé ọdún rẹ kì yóò ní òpin.” 13Èwo nínú àwọn angẹli ní a gbọ́ pé Ọlọ́run fi ìgbà kan wí fún pé,
“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ”? 14Kì í ha á ṣe ẹ̀mí tí ń jíṣẹ́ ni àwọn angẹli í ṣe bí; tí a rán lọ síta láti máa ṣiṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.