Native Bible

Hebrews 1:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó tún sọ pé, “Ní àtètèkọ́ṣe, ìwọ Olúwa, ìwọ fi ìdí ayé sọlẹ̀, àwọn ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ.

Hebrews 1:10 in English

Hebrews 1:10 · Berean Standard Bible

And: “In the beginning, O Lord, You laid the foundations of the earth, and the heavens are the work of Your hands.

Context

8Ṣùgbọ́n ó sọ nípa tí Ọmọ rẹ̀ pé, “Ìtẹ́ rẹ, Ọlọ́run, láé àti láéláé ni, ọ̀pá aládé òdodo ni ọ̀pá ìjọba rẹ. 9Ìwọ fẹ́ òdodo, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kórìíra iṣẹ́ búburú; nítorí èyí ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ ṣe fi àmì òróró ayọ̀ yàn ọ tí ó gbé ọ ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.” 10Ó tún sọ pé, “Ní àtètèkọ́ṣe, ìwọ Olúwa, ìwọ fi ìdí ayé sọlẹ̀, àwọn ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ. 11Wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà síbẹ̀ gbogbo wọn ni yóò di àkísà bí ẹ̀wù. 12Ní kíká ni ìwọ yóò ká wọn bí aṣọ, bí ìpààrọ̀ aṣọ ni a ó sì pààrọ̀ wọn. Ṣùgbọ́n ìwọ fúnra rẹ̀ kì yóò yípadà àti pé ọdún rẹ kì yóò ní òpin.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.