Esra 8:27
Ezra 8:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ogún ago wúrà tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún (1,000) dariki, àti ohun èlò idẹ dáradára méjì ti ó ni iye lórí bí i wúrà.
Ezra 8:27 in English
Ezra 8:27 · Berean Standard Bible
20 gold bowls valued at 1,000 darics,* and two articles of fine polished bronze, as precious as gold.
Context
25mo sì fi òsùwọ̀n wọn ọrẹ fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò tí ọba, àti ti àwọn ìgbìmọ̀, àti ti àwọn ìjòyè, àti ti gbogbo ọmọ Israẹli tí ó wà níbẹ̀, tí wọ́n gbe sílẹ̀ fún ilé Ọlọ́run wa. 26Mo fi òsùwọ̀n wọn ẹgbẹ̀ta lé láàádọ́ta (650) tálẹ́ǹtì fàdákà, àti ohun èlò fàdákà tí ó wọn ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì, ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà, 27ogún ago wúrà tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún (1,000) dariki, àti ohun èlò idẹ dáradára méjì ti ó ni iye lórí bí i wúrà. 28Mo wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin àti àwọn ohun èlò wọ̀nyí ni a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa. Fàdákà àti wúrà sì jẹ́ ọrẹ àtinúwá sí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín. 29Ẹ máa tọ́jú wọn dáradára títí ẹ̀yin yóò fi fi òsùwọ̀n wọ̀n wọ́n jáde kúrò ni ilé Olúwa ni Jerusalẹmu ní iwájú àwọn aṣáájú, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, àti ní iwájú olórí ìdílé gbogbo ni Israẹli.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.