Native Bible

Ezra 8:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin àti àwọn ohun èlò wọ̀nyí ni a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa. Fàdákà àti wúrà sì jẹ́ ọrẹ àtinúwá sí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín.

Ezra 8:28 in English

Ezra 8:28 · Berean Standard Bible

Then I told them, “You are holy to the LORD, and these articles are holy. The silver and gold are a freewill offering to the LORD, the God of your fathers.

Context

26Mo fi òsùwọ̀n wọn ẹgbẹ̀ta lé láàádọ́ta (650) tálẹ́ǹtì fàdákà, àti ohun èlò fàdákà tí ó wọn ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì, ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà, 27ogún ago wúrà tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún (1,000) dariki, àti ohun èlò idẹ dáradára méjì ti ó ni iye lórí bí i wúrà. 28Mo wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin àti àwọn ohun èlò wọ̀nyí ni a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa. Fàdákà àti wúrà sì jẹ́ ọrẹ àtinúwá sí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín. 29Ẹ máa tọ́jú wọn dáradára títí ẹ̀yin yóò fi fi òsùwọ̀n wọ̀n wọ́n jáde kúrò ni ilé Olúwa ni Jerusalẹmu ní iwájú àwọn aṣáájú, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, àti ní iwájú olórí ìdílé gbogbo ni Israẹli.” 30Nígbà náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi gba fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ́ tí a ti wọ̀n jáde fún kíkó lọ sí ilé Ọlọ́run wa ní Jerusalẹmu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.