Native Bible

Ezra 8:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo fi òsùwọ̀n wọn ẹgbẹ̀ta lé láàádọ́ta (650) tálẹ́ǹtì fàdákà, àti ohun èlò fàdákà tí ó wọn ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì, ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà,

Ezra 8:26 in English

Ezra 8:26 · Berean Standard Bible

I weighed out into their hands 650 talents of silver,* articles of silver weighing 100 talents,* 100 talents of gold,*

Context

24Nígbà náà ni mo ya àwọn àlùfáà tó jẹ́ aṣáájú méjìlá sọ́tọ̀, pẹ̀lú Ṣerebiah, Haṣabiah àti mẹ́wàá lára àwọn arákùnrin wọn, 25mo sì fi òsùwọ̀n wọn ọrẹ fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò tí ọba, àti ti àwọn ìgbìmọ̀, àti ti àwọn ìjòyè, àti ti gbogbo ọmọ Israẹli tí ó wà níbẹ̀, tí wọ́n gbe sílẹ̀ fún ilé Ọlọ́run wa. 26Mo fi òsùwọ̀n wọn ẹgbẹ̀ta lé láàádọ́ta (650) tálẹ́ǹtì fàdákà, àti ohun èlò fàdákà tí ó wọn ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì, ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà, 27ogún ago wúrà tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún (1,000) dariki, àti ohun èlò idẹ dáradára méjì ti ó ni iye lórí bí i wúrà. 28Mo wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin àti àwọn ohun èlò wọ̀nyí ni a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa. Fàdákà àti wúrà sì jẹ́ ọrẹ àtinúwá sí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.