Native Bible

Ezra 8:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

mo sì fi òsùwọ̀n wọn ọrẹ fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò tí ọba, àti ti àwọn ìgbìmọ̀, àti ti àwọn ìjòyè, àti ti gbogbo ọmọ Israẹli tí ó wà níbẹ̀, tí wọ́n gbe sílẹ̀ fún ilé Ọlọ́run wa.

Ezra 8:25 in English

Ezra 8:25 · Berean Standard Bible

and I weighed out to them the contribution of silver and gold and the articles that the king, his counselors, his leaders, and all the Israelites there had offered for the house of our God.

Context

23Bẹ́ẹ̀ ni a sì gbààwẹ̀, a sì bẹ̀bẹ̀ fún èyí lọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, òun sì gbọ́ àdúrà wa. 24Nígbà náà ni mo ya àwọn àlùfáà tó jẹ́ aṣáájú méjìlá sọ́tọ̀, pẹ̀lú Ṣerebiah, Haṣabiah àti mẹ́wàá lára àwọn arákùnrin wọn, 25mo sì fi òsùwọ̀n wọn ọrẹ fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò tí ọba, àti ti àwọn ìgbìmọ̀, àti ti àwọn ìjòyè, àti ti gbogbo ọmọ Israẹli tí ó wà níbẹ̀, tí wọ́n gbe sílẹ̀ fún ilé Ọlọ́run wa. 26Mo fi òsùwọ̀n wọn ẹgbẹ̀ta lé láàádọ́ta (650) tálẹ́ǹtì fàdákà, àti ohun èlò fàdákà tí ó wọn ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì, ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà, 27ogún ago wúrà tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún (1,000) dariki, àti ohun èlò idẹ dáradára méjì ti ó ni iye lórí bí i wúrà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.