Esra 8:23
Ezra 8:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni a sì gbààwẹ̀, a sì bẹ̀bẹ̀ fún èyí lọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, òun sì gbọ́ àdúrà wa.
Ezra 8:23 in English
Ezra 8:23 · Berean Standard Bible
So we fasted and petitioned our God about this, and He granted our request.
Context
21Níbẹ̀, ní ẹ̀bá odò Ahafa, mo kéde àwẹ̀, kí a ba à le rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, kí a sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìrìnàjò àìléwu fún wa àti àwọn ọmọ wa àti fún gbogbo ohun ìní wa. 22Mo tijú láti béèrè lọ́wọ́ ọba fún àwọn jagunjagun orí ilẹ̀, àti ti orí ẹṣin láti dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ní ọ̀nà wa, nítorí àti sọ fún ọba pé, “Ọwọ́ àánú Ọlọ́run wà ní ara gbogbo ẹni tí ó gbé ojú sókè sí i, ṣùgbọ́n ìbínú ńlá rẹ wà lórí ẹni tó kọ̀ ọ́ sílẹ̀.” 23Bẹ́ẹ̀ ni a sì gbààwẹ̀, a sì bẹ̀bẹ̀ fún èyí lọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, òun sì gbọ́ àdúrà wa. 24Nígbà náà ni mo ya àwọn àlùfáà tó jẹ́ aṣáájú méjìlá sọ́tọ̀, pẹ̀lú Ṣerebiah, Haṣabiah àti mẹ́wàá lára àwọn arákùnrin wọn, 25mo sì fi òsùwọ̀n wọn ọrẹ fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò tí ọba, àti ti àwọn ìgbìmọ̀, àti ti àwọn ìjòyè, àti ti gbogbo ọmọ Israẹli tí ó wà níbẹ̀, tí wọ́n gbe sílẹ̀ fún ilé Ọlọ́run wa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.