Native Bible

Ezekiel 7:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Wọ́n ti fọn ìpè ogun, tí wọ́n sì pèsè ohun gbogbo sílẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò lọ ojú ogun, nítorí ìbínú gbígbóná mi ti wà lórí gbogbo ènìyàn.

Ezekiel 7:14 in English

Ezekiel 7:14 · Berean Standard Bible

They have blown the trumpet and made everything ready, but no one goes to war, for My wrath is upon the whole multitude.

Context

12Àkókò náà dé! Ọjọ́ náà ti dé! Kí òǹrajà má ṣe yọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ki òǹtajà má ṣe ṣọ̀fọ̀; nítorí, ìbínú gbígbóná wà lórí gbogbo ènìyàn. 13Nítorí pé òǹtajà kì yóò rí gbà padà dúkìá èyí tó tà níwọ̀n ìgbà ti àwọn méjèèjì bá wà láààyè. Nítorí ìran tó kan gbogbo ènìyàn yìí kò ní yí padà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò gba ara rẹ̀ là. 14“ ‘Wọ́n ti fọn ìpè ogun, tí wọ́n sì pèsè ohun gbogbo sílẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò lọ ojú ogun, nítorí ìbínú gbígbóná mi ti wà lórí gbogbo ènìyàn. 15Idà wà ní ìta, àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn wà nílé, idà yóò pa ẹni tó bá wà ní orílẹ̀-èdè, àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn yóò pa ẹni tó bá wà ní ìlú. 16Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà, wọn yóò sì wà lórí òkè. Bí i àdàbà inú àfonífojì, gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀, olúkúlùkù nítorí àìṣedéédéé rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.