Esekiẹli 7:12
Ezekiel 7:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àkókò náà dé! Ọjọ́ náà ti dé! Kí òǹrajà má ṣe yọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ki òǹtajà má ṣe ṣọ̀fọ̀; nítorí, ìbínú gbígbóná wà lórí gbogbo ènìyàn.
Ezekiel 7:12 in English
Ezekiel 7:12 · Berean Standard Bible
The time has come; the day has arrived. Let the buyer not rejoice and the seller not mourn, for wrath is upon the whole multitude.
Context
10“ ‘Ọjọ́ náà dé!
Kíyèsi ó ti dé!
Ìparun ti bú jáde,
ọ̀pá ti tanná,
ìgbéraga ti rúdí! 11Ìwà ipá ti di ọ̀pá ìwà búburú;
ọ̀pá láti jẹ ẹni búburú ní ìyà.
Kò sí nínú wọn tí yóò ṣẹ́kù,
tàbí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn,
kò sí nínú ọrọ̀ wọn,
kò sí ohun tí ó ní iye. 12Àkókò náà dé!
Ọjọ́ náà ti dé!
Kí òǹrajà má ṣe yọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ki òǹtajà má ṣe ṣọ̀fọ̀;
nítorí, ìbínú gbígbóná wà lórí gbogbo ènìyàn. 13Nítorí pé òǹtajà kì yóò rí gbà padà
dúkìá èyí tó tà
níwọ̀n ìgbà ti àwọn méjèèjì bá wà láààyè.
Nítorí ìran tó kan gbogbo ènìyàn yìí
kò ní yí padà.
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kò sí ọ̀kan nínú wọn
tí yóò gba ara rẹ̀ là. 14“ ‘Wọ́n ti fọn ìpè ogun,
tí wọ́n sì pèsè ohun gbogbo sílẹ̀,
ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò lọ ojú ogun,
nítorí ìbínú gbígbóná mi ti wà lórí gbogbo ènìyàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.