Esekiẹli 7:10
Ezekiel 7:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Ọjọ́ náà dé! Kíyèsi ó ti dé! Ìparun ti bú jáde, ọ̀pá ti tanná, ìgbéraga ti rúdí!
Ezekiel 7:10 in English
Ezekiel 7:10 · Berean Standard Bible
Behold, the day is here! It has come! Doom has gone out, the rod has budded, arrogance has bloomed.
Context
8Mo ṣetán láti tú ìbínú gbígbóná mi lé ọ lórí
àti láti lo ìbínú mi lórí rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ,
èmi yóò sì dá ọ lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ
àti gẹ́gẹ́ bí ìwà ìríra rẹ ni èmi yóò sì san án fún ọ. 9Ojú mi kò ní i dá ọ sí,
Èmi kò sì ní wò ọ́ pẹ̀lú àánú;
èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ
àti fún gbogbo ìwà ìríra tí wà láàrín rẹ.
“ ‘Nígbà náà ní ẹ o mọ̀ pé Èmi Olúwa lo kọlù yín. 10“ ‘Ọjọ́ náà dé!
Kíyèsi ó ti dé!
Ìparun ti bú jáde,
ọ̀pá ti tanná,
ìgbéraga ti rúdí! 11Ìwà ipá ti di ọ̀pá ìwà búburú;
ọ̀pá láti jẹ ẹni búburú ní ìyà.
Kò sí nínú wọn tí yóò ṣẹ́kù,
tàbí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn,
kò sí nínú ọrọ̀ wọn,
kò sí ohun tí ó ní iye. 12Àkókò náà dé!
Ọjọ́ náà ti dé!
Kí òǹrajà má ṣe yọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ki òǹtajà má ṣe ṣọ̀fọ̀;
nítorí, ìbínú gbígbóná wà lórí gbogbo ènìyàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.