Esekiẹli 7:15
Ezekiel 7:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Idà wà ní ìta, àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn wà nílé, idà yóò pa ẹni tó bá wà ní orílẹ̀-èdè, àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn yóò pa ẹni tó bá wà ní ìlú.
Ezekiel 7:15 in English
Ezekiel 7:15 · Berean Standard Bible
The sword is outside; plague and famine are within. Those in the country will die by the sword, and those in the city will be devoured by famine and plague.
Context
13Nítorí pé òǹtajà kì yóò rí gbà padà
dúkìá èyí tó tà
níwọ̀n ìgbà ti àwọn méjèèjì bá wà láààyè.
Nítorí ìran tó kan gbogbo ènìyàn yìí
kò ní yí padà.
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kò sí ọ̀kan nínú wọn
tí yóò gba ara rẹ̀ là. 14“ ‘Wọ́n ti fọn ìpè ogun,
tí wọ́n sì pèsè ohun gbogbo sílẹ̀,
ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò lọ ojú ogun,
nítorí ìbínú gbígbóná mi ti wà lórí gbogbo ènìyàn. 15Idà wà ní ìta,
àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn wà nílé,
idà yóò pa ẹni tó bá wà ní orílẹ̀-èdè,
àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn yóò pa ẹni tó bá wà ní ìlú. 16Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà,
wọn yóò sì wà lórí òkè.
Bí i àdàbà inú àfonífojì,
gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀,
olúkúlùkù nítorí àìṣedéédéé rẹ̀. 17Gbogbo ọwọ́ yóò rọ,
gbogbo orúnkún yóò di aláìlágbára bí omi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.