Native Bible

Ezekiel 7:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo ọwọ́ yóò rọ, gbogbo orúnkún yóò di aláìlágbára bí omi.

Ezekiel 7:17 in English

Ezekiel 7:17 · Berean Standard Bible

Every hand will go limp, and every knee will turn to water.

Context

15Idà wà ní ìta, àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn wà nílé, idà yóò pa ẹni tó bá wà ní orílẹ̀-èdè, àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn yóò pa ẹni tó bá wà ní ìlú. 16Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà, wọn yóò sì wà lórí òkè. Bí i àdàbà inú àfonífojì, gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀, olúkúlùkù nítorí àìṣedéédéé rẹ̀. 17Gbogbo ọwọ́ yóò rọ, gbogbo orúnkún yóò di aláìlágbára bí omi. 18Wọn yóò wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀rù yóò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀, ìtìjú yóò mù wọn, wọn yóò sì fá irun wọn. 19“ ‘Wọn yóò dà fàdákà wọn sí ojú pópó, wúrà wọn yóò sì dàbí èérí fàdákà àti wúrà wọn kò ní le gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná Olúwa. Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùn tàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹ nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.