Native Bible

Ezekiel 7:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà, wọn yóò sì wà lórí òkè. Bí i àdàbà inú àfonífojì, gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀, olúkúlùkù nítorí àìṣedéédéé rẹ̀.

Ezekiel 7:16 in English

Ezekiel 7:16 · Berean Standard Bible

The survivors will escape and live in the mountains, moaning like doves of the valley, each for his own iniquity.

Context

14“ ‘Wọ́n ti fọn ìpè ogun, tí wọ́n sì pèsè ohun gbogbo sílẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò lọ ojú ogun, nítorí ìbínú gbígbóná mi ti wà lórí gbogbo ènìyàn. 15Idà wà ní ìta, àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn wà nílé, idà yóò pa ẹni tó bá wà ní orílẹ̀-èdè, àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn yóò pa ẹni tó bá wà ní ìlú. 16Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà, wọn yóò sì wà lórí òkè. Bí i àdàbà inú àfonífojì, gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀, olúkúlùkù nítorí àìṣedéédéé rẹ̀. 17Gbogbo ọwọ́ yóò rọ, gbogbo orúnkún yóò di aláìlágbára bí omi. 18Wọn yóò wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀rù yóò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀, ìtìjú yóò mù wọn, wọn yóò sì fá irun wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.