Native Bible

Ezekiel 30:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kuṣi àti Puti, Libia, Ludi àti gbogbo Arabia, Kubu àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó mulẹ̀ yóò ṣubú nípa idà pẹ̀lú Ejibiti.

Ezekiel 30:5 in English

Ezekiel 30:5 · Berean Standard Bible

Cush, Put, and Lud,* and all the various peoples, as well as Libya and the men of the covenant land, will fall with Egypt by the sword.

Context

3Nítorí ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí àní ọjọ́ Olúwa súnmọ́ tòsí, ọjọ́ tí ọjọ́ ìkùùkuu ṣú dúdú, àsìkò ìparun fún àwọn kèfèrí. 4Idà yóò wá sórí Ejibiti ìrora ńlá yóò sì wá sórí Kuṣi. Nígbà tí àwọn tí a pa yóò ṣubú ní Ejibiti wọn yóò kò ọrọ̀ rẹ̀ lọ ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóò sì wó lulẹ̀. 5Kuṣi àti Puti, Libia, Ludi àti gbogbo Arabia, Kubu àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó mulẹ̀ yóò ṣubú nípa idà pẹ̀lú Ejibiti. 6“ ‘Èyí yìí ní Olúwa wí: “ ‘Àwọn àlejò Ejibiti yóò ṣubú agbára ìgbéraga rẹ yóò kùnà láti Migdoli títí dé Siene, wọn yóò ti ipa idà ṣubú nínú rẹ; ní Olúwa Olódùmarè wí. 7Wọn yóò sì wà lára àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro, ìlú rẹ yóò sì wà ní ara àwọn ìlú tí ó di ahoro.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.