Esekiẹli 30:6
Ezekiel 30:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Èyí yìí ní Olúwa wí: “ ‘Àwọn àlejò Ejibiti yóò ṣubú agbára ìgbéraga rẹ yóò kùnà láti Migdoli títí dé Siene, wọn yóò ti ipa idà ṣubú nínú rẹ; ní Olúwa Olódùmarè wí.
Ezekiel 30:6 in English
Ezekiel 30:6 · Berean Standard Bible
For this is what the LORD says: The allies of Egypt will fall, and her proud strength will collapse. From Migdol to Syene * they will fall by the sword within her, declares the Lord GOD.
Context
4Idà yóò wá sórí Ejibiti
ìrora ńlá yóò sì wá sórí Kuṣi.
Nígbà tí àwọn tí a pa yóò ṣubú ní Ejibiti
wọn yóò kò ọrọ̀ rẹ̀ lọ
ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóò sì wó lulẹ̀. 5Kuṣi àti Puti, Libia, Ludi àti gbogbo Arabia, Kubu àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó mulẹ̀ yóò ṣubú nípa idà pẹ̀lú Ejibiti. 6“ ‘Èyí yìí ní Olúwa wí:
“ ‘Àwọn àlejò Ejibiti yóò ṣubú
agbára ìgbéraga rẹ yóò kùnà
láti Migdoli títí dé Siene,
wọn yóò ti ipa idà ṣubú nínú rẹ;
ní Olúwa Olódùmarè wí. 7Wọn yóò sì wà
lára àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro,
ìlú rẹ yóò sì wà
ní ara àwọn ìlú tí ó di ahoro. 8Lẹ́yìn náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,
nígbà tí mo bá gbé iná kalẹ̀ ní Ejibiti
tí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá parun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.