Esekiẹli 30:8
Ezekiel 30:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa, nígbà tí mo bá gbé iná kalẹ̀ ní Ejibiti tí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá parun.
Ezekiel 30:8 in English
Ezekiel 30:8 · Berean Standard Bible
Then they will know that I am the LORD when I set fire to Egypt and all her helpers are shattered.
Context
6“ ‘Èyí yìí ní Olúwa wí:
“ ‘Àwọn àlejò Ejibiti yóò ṣubú
agbára ìgbéraga rẹ yóò kùnà
láti Migdoli títí dé Siene,
wọn yóò ti ipa idà ṣubú nínú rẹ;
ní Olúwa Olódùmarè wí. 7Wọn yóò sì wà
lára àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro,
ìlú rẹ yóò sì wà
ní ara àwọn ìlú tí ó di ahoro. 8Lẹ́yìn náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,
nígbà tí mo bá gbé iná kalẹ̀ ní Ejibiti
tí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá parun. 9“ ‘Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kuṣi tí ó wà nínú àlàáfíà. Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Ejibiti. Kíyèsi i, ó dé. 10“ ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Èmi yóò mú òpin bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn
ènìyàn Ejibiti láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.