Esekiẹli 30:10
Ezekiel 30:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Èmi yóò mú òpin bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn Ejibiti láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli.
Ezekiel 30:10 in English
Ezekiel 30:10 · Berean Standard Bible
This is what the Lord GOD says: I will put an end to the hordes of Egypt by the hand of Nebuchadnezzar king of Babylon.
Context
8Lẹ́yìn náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,
nígbà tí mo bá gbé iná kalẹ̀ ní Ejibiti
tí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá parun. 9“ ‘Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kuṣi tí ó wà nínú àlàáfíà. Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Ejibiti. Kíyèsi i, ó dé. 10“ ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Èmi yóò mú òpin bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn
ènìyàn Ejibiti láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli. 11Òun àti àwọn ológun rẹ̀
ẹ̀rù àwọn orílẹ̀-èdè
ní a o mú wá láti pa ilẹ̀ náà run.
Wọn yóò fa idà wọn yọ sí Ejibiti
ilẹ̀ náà yóò sì kún fún àwọn tí a pa. 12Èmi yóò mú kí àwọn odò Naili gbẹ,
Èmi yóò sì ta ilẹ̀ náà fún àwọn ènìyàn búburú:
láti ọwọ́ àwọn àjèjì ènìyàn,
Èmi yóò jẹ́ kí ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tí ó wá nínú rẹ ṣòfò.
Èmi Olúwa ni ó ti sọ ọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.