Esekiẹli 30:11
Ezekiel 30:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òun àti àwọn ológun rẹ̀ ẹ̀rù àwọn orílẹ̀-èdè ní a o mú wá láti pa ilẹ̀ náà run. Wọn yóò fa idà wọn yọ sí Ejibiti ilẹ̀ náà yóò sì kún fún àwọn tí a pa.
Ezekiel 30:11 in English
Ezekiel 30:11 · Berean Standard Bible
He and his people with him, the most ruthless of the nations, will be brought in to destroy the land. They will draw their swords against Egypt and fill the land with the slain.
Context
9“ ‘Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kuṣi tí ó wà nínú àlàáfíà. Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Ejibiti. Kíyèsi i, ó dé. 10“ ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Èmi yóò mú òpin bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn
ènìyàn Ejibiti láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli. 11Òun àti àwọn ológun rẹ̀
ẹ̀rù àwọn orílẹ̀-èdè
ní a o mú wá láti pa ilẹ̀ náà run.
Wọn yóò fa idà wọn yọ sí Ejibiti
ilẹ̀ náà yóò sì kún fún àwọn tí a pa. 12Èmi yóò mú kí àwọn odò Naili gbẹ,
Èmi yóò sì ta ilẹ̀ náà fún àwọn ènìyàn búburú:
láti ọwọ́ àwọn àjèjì ènìyàn,
Èmi yóò jẹ́ kí ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tí ó wá nínú rẹ ṣòfò.
Èmi Olúwa ni ó ti sọ ọ́. 13“ ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Èmi yóò pa àwọn òrìṣà run,
Èmi yóò sì mú kí òpin dé bá ère gbígbẹ́ ni Memfisi.
Kò ní sí ọmọ-aládé mọ́ ní Ejibiti,
Èmi yóò mú kí ìbẹ̀rù gba gbogbo ilẹ̀ náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.