Esekiẹli 30:3
Ezekiel 30:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí àní ọjọ́ Olúwa súnmọ́ tòsí, ọjọ́ tí ọjọ́ ìkùùkuu ṣú dúdú, àsìkò ìparun fún àwọn kèfèrí.
Ezekiel 30:3 in English
Ezekiel 30:3 · Berean Standard Bible
For the day is near, the Day of the LORD is near. It will be a day of clouds, a time of doom for the nations.*
Context
1Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá: wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Hu, kí o sì wí pé,
“Ó ṣe fún ọjọ́ náà!” 3Nítorí ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí
àní ọjọ́ Olúwa súnmọ́ tòsí,
ọjọ́ tí ọjọ́ ìkùùkuu ṣú dúdú,
àsìkò ìparun fún àwọn kèfèrí. 4Idà yóò wá sórí Ejibiti
ìrora ńlá yóò sì wá sórí Kuṣi.
Nígbà tí àwọn tí a pa yóò ṣubú ní Ejibiti
wọn yóò kò ọrọ̀ rẹ̀ lọ
ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóò sì wó lulẹ̀. 5Kuṣi àti Puti, Libia, Ludi àti gbogbo Arabia, Kubu àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó mulẹ̀ yóò ṣubú nípa idà pẹ̀lú Ejibiti.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.